Ezekiel 45:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo wọn apá kan tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10), níbẹ̀ ni ilé mímọ́ yóo wà, yóo jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu ìwọn yi ni iwọ o wọ̀n ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbarun ni ibú; ati ninu rẹ̀ ni ibi-mimọ́ yio wà, ibi-mimọ́ julọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún OLÚWA yóò wà, ìyẹn ibi mímọ́ jùlọ.