Ezekiel 45:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà, yóo wà fún àwọn alufaa, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, tí wọ́n sì ń dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ iranṣẹ. Ibẹ̀ ni wọn yóo kọ́ ilé wọn sí, ibẹ̀ ni yóo sì jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ fún ibi mímọ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ti o mọ́ ninu ilẹ na yio jẹ ti awọn alufa, awọn iranṣẹ ibi-mimọ́, ti yio sunmọ lati ṣe iránṣẹ fun Oluwa: yio si jẹ àye fun ile wọn, ati ibi-mimọ́ fun ibi-mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú OLÚWA. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé OLÚWA.