Ezekiel 45:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wọn ibòmíràn tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10). Ibẹ̀ ni yóo wà fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, ibẹ̀ ni wọn óo máa gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigun, ati ti ẹgbãrun ni ibú, ni awọn Lefi, pẹlu awọn iranṣẹ ile na, ni ogún yará, fun ara wọn, ni ini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ yóò jẹ́ ti àwọn ará Léfì, tí ó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.