Ezekiel 45:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo ya apá kan sọ́tọ̀ tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), ilẹ̀ yìí yóo wà fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ini ilu na li ẹnyin o yàn ẹgbarun ni ibú, ati ẹgba mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, lẹba ọrẹ ipín mimọ́ na: yio jẹ ti gbogbo ile Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.