Ezekiel 45:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọba Israẹli, ẹ má hùwà ipá ati ìninilára mọ́, ẹ máa hùwà ẹ̀tọ́ ati òdodo, ẹ má lé àwọn eniyan mi jáde mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ki o to fun nyin, ẹnyin olori Israeli: ẹ mu ìwa ipa irẹ́jẹ kuro, ki ẹ si mu idajọ ati ododo ṣẹ, mu ilọ́nilọwọgbà nyin kuro lọdọ awọn enia mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èyí yìí ni OLÚWA Ọba wí: Ìwọ ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ aládé tí Ísírẹ́lì! Fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ rẹ sílẹ̀ kí ó sì se èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Dáwọ́ gbígbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni OLÚWA Ọba sọ.