Ezekiel 46:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ àsè ati ìgbà àjọ̀dún, ìwọ̀n eefa ọkà kan ni wọn óo fi rúbọ pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù kan, ìwọ̀n eefa ọkà kan pẹlu àgbò kan, ati ìwọ̀n eefa ọkà tí eniyan bá lágbára pẹlu ọ̀dọ́ aguntan, ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi ìwọ̀n òróró hini kọ̀ọ̀kan ti ìwọ̀n eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu awọn asè ati ninu awọn ajọ, ọrẹ-ẹbọ jijẹ yio jẹ efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ-malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan pẹ̀lú àgbò kan, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá se wu onílúlùkù, Pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan.