Ezekiel 46:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí ọba bá pèsè ẹbọ ọrẹ àtinúwá, kì báà ṣe ẹbọ sísun, tabi ẹbọ alaafia, ni ọrẹ àtinúwá fún OLUWA tí ó pèsè, wọn yóo ṣí ẹnubodè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn fún un, yóo sì rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia rẹ̀ bíi ti ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà yóo jáde, wọn óo sì ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati olori na yio ba si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun atinuwá, tabi ọrẹ-ẹbọ idupẹ atinuwá fun Oluwa, ẹnikan yio si ṣi ilẹkun ti o kọjusi ila-õrun fun u, yio si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ idupẹ rẹ̀, bi o ti ṣe li ọjọ-isimi: yio si jade; ati lẹhin ijadelọ rẹ̀ ẹnikan yio tì ilẹkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọmọ aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún OLÚWA yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn ni kí ó wà ni sísí sílẹ̀ fún-un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, oun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu ọ̀nà.