Ezekiel 46:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹbọ ohun jíjẹ tí yóo máa pèsè pẹlu rẹ̀ láràárọ̀ ni: ìdámẹ́fà eefa ìyẹ̀fun ati ìdámẹ́ta hini òróró tí wọn yóo fi máa po ìyẹ̀fun náà fún ẹbọ ohun jíjẹ fún OLUWA. Èyí ni yóo jẹ́ ìlànà fún ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun u lorowurọ̀, idamẹfa efa, ati idamẹfa hini ororo kan, lati fi pò iyẹfun daradara na; ọrẹ-ẹbọ jijẹ nigbagbogbo nipa aṣẹ lailai fun Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú éfà àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún OLÚWA jẹ́ ìlànà tí ó wà títí.