Ezekiel 46:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ọba bá fún ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di ti àwọn ọmọ rẹ̀, ó di ohun ìní wọn tí wọ́n jogún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi olori na ba fi ẹbùn fun ẹnikẹni ninu awọn ọmọ rẹ̀, ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀; yio jẹ ini wọn nipa ijogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA Ọba sọ: Tí ọmọ aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tíwọn nípa ogún jíjẹ.