Ezekiel 46:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di tirẹ̀ títí di ọjọ́ tí yóo gba òmìnira; láti ọjọ́ náà ni ilẹ̀ náà yóo ti pada di ti ọba. Àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan ni wọ́n lè jogún ilẹ̀ rẹ̀ títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si fi ẹbùn ninu ini rẹ̀ fun ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, nigbana yio jẹ tirẹ̀ titi di ọdun omnira; yio si tun pada di ti olori na: ṣugbọn ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀ fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọkan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pa mọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀; Lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; Ó jẹ́ tiwọn.