Ezekiel 46:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba kò gbọdọ̀ gbà ninu ilẹ̀ àwọn ará ìlú láti ni wọ́n lára; ninu ilẹ̀ tirẹ̀ ni kí ó ti pín ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má baà gba ilẹ̀ ọ̀kankan ninu àwọn eniyan mi kúrò lọ́wọ́ wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olori na kì yio si fi ipá mu ninu ogún awọn enia lati le wọn jade kuro ninu ini wọn, yio fi ogún fun awọn ọmọ rẹ̀ lara ini ti ontikalarẹ̀: ki awọn enia mi ki o má ba tuká, olukuluku kuro ni ini rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ aládé kò gbọdọ̀ mú ìkankan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma baà ya ìkankan kúrò lára ìní rẹ̀’ ”