Ezekiel 46:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yàrá àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni ọba yóo gbà wọlé, yóo sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ẹnu ọ̀nà. Àwọn alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ti alaafia rẹ̀. Ọba yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbájáde, yóo sì jáde; ṣugbọn wọn kò ní ti ìlẹ̀kùn náà títí di ìrọ̀lẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olori na yio si ba ẹnu-ọ̀na iloro ti ẹnu-ọ̀na ode wọle, yio si duro nibi opó ẹnu-ọ̀na, awọn alufa yio si pèse ọrẹ ẹbọ sisun rẹ̀ ati ọrẹ ẹbọ idupẹ rẹ̀, on o si ma sìn ni iloro ẹnu-ọ̀na: yio si jade wá; a kì yio si tì ẹnu-ọ̀na titi di aṣalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kangun sí àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ilẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́.