Ezekiel 46:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA wá sọ fún mi pé, “Ní ibí yìí ni àwọn alufaa yóo ti máa se ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ibẹ̀ ni wọn yóo sì ti máa ṣe burẹdi fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọn má baà kó wọn jáde wá sí gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, kí wọn má baà fi ohun mímọ́ kó bá àwọn eniyan.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Eyi ni ibiti awọn alufa yio ma sè ọrẹ irekọja ati ọrẹ ẹ̀ṣẹ, nibiti nwọn o ma yan ọrẹ jijẹ; ki nwọn má ba gbe wọn jade si agbalá ode, lati sọ awọn enia di mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má se jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”