Ezekiel 46:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹbọ ọkà pẹlu àgbò yóo jẹ́ ìwọ̀n eefa kan. Ìwọ̀n ọkà pẹlu iye ọ̀dọ́ aguntan tí ó bá lágbára ni yóo fi rú ẹbọ ọkà pẹlu ọ̀dọ́ aguntan. Ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi òróró hini kọ̀ọ̀kan ti eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọrẹ ẹbọ jijẹ yio jẹ efà kan fun agbò kan, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú éfà kọ̀ọ̀kan.