Ezekiel 46:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará ìlú bá wá siwaju OLUWA ní àkókò àjọ̀dún, ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà apá àríwá wọlé, ẹnu ọ̀nà gúsù ni ó gbọdọ̀ gbà jáde, ẹni tí ó bá sì gba ẹnu ọ̀nà gúsù wọlé, ẹnu ọ̀nà àríwá ni ó gbọdọ̀ gbà jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ẹnu ọ̀nà tó gbà wọlé jáde. Tààrà ni kí olukuluku máa lọ títí yóo fi jáde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati enia ilẹ na yio ba si wá siwaju Oluwa ni awọn apejọ ọ̀wọ, ẹniti o ba ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa wọle lati sìn, yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu jade; ẹniti o ba si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu wọle yio si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa jade; kì yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ti o ba wọle jade, ṣugbọn yio jade lodi keji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá ṣíwájú OLÚWA ni àwọn àjọ tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà gúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gba tí ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé padà, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.