Ezekiel 47:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin náà bá mú mi pada wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili, mo sì rí i tí omi kan ń sun láti abẹ́ ìlẹ̀kùn àbájáde ó ń ṣàn lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ìhà ìlà oòrùn ni tẹmpili kọjú sí. Omi náà ń ṣàn láti apá gúsù ibi ìlẹ̀kùn àbájáde tí ó wà ni ìhà gúsù pẹpẹ ìrúbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mu mi padà wá si ibi ilẹkùn ile na; si kiyesi i, omi ntù jade lati abẹ iloro ile na nihà ila-õrun: nitori iwaju ile na wà ni ila-õrun, omi si nwalẹ lati abẹ apa ọtun ile na, ni gusu pẹpẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹ́ḿpìlì náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹ́ḿpìlì náà sí apá ìhà ìlà oòrùn (nítorí tẹ́ḿpìlì náà dojúkọ ìhà ìlà oòrùn) Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúsù tẹ́ḿpìlì náà, ní ìhà gúsù pẹpẹ.