Ezekiel 47:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn apẹja yóo dúró létí òkun láti Engedi títí dé Enegilaimu, ibẹ̀ yóo di ibi tí wọn yóo ti máa na àwọ̀n wọn sá sí. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóo wà níbẹ̀ bí ẹja inú Òkun Ńlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe pe, Awọn apẹja yio duro lori rẹ̀ lati Engedi titi de Eneglaimu; nwọn o jẹ ibi lati nà àwọn si; ẹja wọn o dabi iru wọn, bi ẹja okun-nla, lọpọlọpọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti Éńgédì títí dé Énégíláémù àyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Orísìírísìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi òkun ńlá.