Ezekiel 47:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oríṣìíríṣìí igi eléso yóo hù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji odò náà: ewé àwọn igi náà kò ní rọ, bẹ́ẹ̀ ni èso wọn kò ní tán. Lóṣooṣù ni wọn yóo máa so èso tuntun nítorí pé láti inú tẹmpili ni omi rẹ̀ yóo ti máa sun jáde wá. Èso wọn yóo wà fún jíjẹ, ewé wọn yóo sì wà fún ìwòsàn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lẹba odò ni eti rẹ̀, ni ihà ihin ati ni ihà ọhun, ni gbogbo igi jijẹ yio hù, ti ewe rẹ̀ kì yio rọ, ti eso rẹ̀ kì yio si run: yio ma so eso titun rẹ̀ li oṣù rẹ̀, nitori omi wọn lati ibi mimọ́ ni nwọn ti ntú jade: eso rẹ̀ yio si jẹ fun jijẹ, ati ewe rẹ̀ fun imunilaradá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò dàgbà ní bèbè odò méjèèjì. Ewé wọn kì yóò sì gbẹ, tàbí ní èso nítorí pé odò láti ibi mímọ́ ń ṣàn sí wọn. Èso wọn yóò dàbí oúnjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”