Ezekiel 47:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ní apá ìhà ìlà oòrùn, ààlà náà yóo lọ láti Hasari Enọni tí ó wà láàrin Haurani ati Damasku, ní ẹ̀gbẹ́ odò Jọdani tí ó wà láàrin Gileadi ati ilẹ̀ Israẹli, títí dé òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì lọ títí dé Tamari. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni ihà ila-õrun ẹ o wọ̀n lati ãrin Haurani, ati lati ãrin Damasku, ati lati ãrin Gileadi, ati lati ãrin ilẹ Israeli lẹba Jordani, lati ãlà titi de okun ila-õrun. Eyi ni ihà ila-õrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ìhà ìlà oòrùn ààlà yóò wá sí àárin Háúránù àti Dámásíkù, lọ sí apá Jọ́dánì láàárin Gílíádì àti ilẹ̀ oòrùn àti títí dé Támárì. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà oòrùn.