Ezekiel 47:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ní ìwọ̀ oòrùn, Òkun Ńlá ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín, yóo lọ títí dé òdìkejì ẹnu ọ̀nà Hamati. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ihà iwọ-õrun pẹlu yio jẹ okun nla lati ãlà bi a ti nlọ si Hamati. Eyi ni ihà iwọ-õrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, òkun ńlá ni yóò jẹ́ ààlà títí dé ibi kan ni òdìkejì lẹ́bàá Hámátì. Èyí yìí ni yóò jẹ ààlà ìhà ìwọ̀ oòrùn.