Ezekiel 47:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo pín in fún ara yín ati fún àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tí wọ́n sì ti bímọ sí ààrin yín. Ẹ óo kà wọ́n sí ọmọ onílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ óo pín ilẹ̀ fún àwọn náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe pe, ìbo ni ẹ o fi pin i ni ogún fun ara nyin, ati fun awọn alejo ti o ṣe atipo lãrin nyin, ti nwọn bi ọmọ lãrin nyin: nwọn o si ri si nyin bi ibilẹ ninu awọn ọmọ Israeli; nwọn o ba nyin pin i li ogún lãrin awọn ẹ̀ya Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò pín gẹ́gẹ́ bí ìní fún ara yín àti fún àwọn àjòjì tí ó ń gbé ní àárin yín tí ó sì ní àwọn ọmọ. Ìwọ yóò sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ àwọn ará Ísírẹ́lì; papọ̀ mọ́ yin ni kí a pín ìní fún wọn ní àárin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.