Ezekiel 47:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin náà lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn, ó mú okùn ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Ó fi wọn ẹgbẹrun igbọnwọ, (mita 450). Ó sì mú mi la odò kan tí ó mù mí dé kókósẹ̀ kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọkunrin na jade sihà ila-õrun, pẹlu okùn kan lọwọ rẹ̀, o si wọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ, o si mu mi là omi na ja; omi na si de kókosẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, o wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kòì jìnjù kókósẹ̀ lọ.