Ezekiel 47:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), mìíràn sí ìsàlẹ̀, odò náà jìn ju ohun tí mo lè là kọjá lọ, nítorí pé ó ti kún sí i, ó jìn tó ohun tí eniyan lè lúwẹ̀ẹ́ ninu rẹ̀. Ó kọjá ohun tí eniyan lè là kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wọ̀n ẹgbẹrun; odò ti nkò le wọ́: nitori omi ti kún, omi ilúwẹ, odò ti kò ṣe rekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsìnyí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, Nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jìn tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni.