Ezekiel 47:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọpọlọpọ ohun ẹlẹ́mìí yóo wà ní ibikíbi tí omi náà bá ti ṣàn kọjá. Ẹja yóo pọ̀ ninu rẹ̀; nítorí pé omi yìí ṣàn lọ sí inú òkun, omi tí ó wà níbẹ̀ yóo di mímọ́ gaara, ohunkohun tí ó bá sì wà ní ibi tí odò yìí bá ti ṣàn kọjá yóo yè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe pe, ohunkohun ti o ba wà lãye ti nrakò, nibikibi ti odò mejeji ba de, yio wà lãye: ọ̀pọlọpọ ẹja yio si de, nitori omi wọnyi yio de ibẹ̀: a o si mu wọn lara dá; ohun gbogbo yio si yè nibikibi ti odò na ba de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ohun alààyè tí o ń rákò yóò máa gbé ní íbikíbi tí odò ti ń ṣàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń ṣàn síbẹ̀ ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń ṣàn gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè.