Ezekiel 48:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí: Ààlà ilẹ̀ náà ní ìhà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etíkun, ó lọ ní apá ọ̀nà Hẹtiloni dé àbáwọ Hamati títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ààlà Damasku, ní òdìkejì Hamati. Ó lọ láti apá ìlà oòrùn títí dé apá ìwọ̀ oòrùn: Ìpín ti Dani yóo jẹ́ ìpín kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
WỌNYI si ni orukọ awọn ẹ̀ya na. Lati opin ariwa titi de ọwọ́ ọ̀na Hetlonu, bi a ba nlọ si Hamati, Hasaenani, leti Damasku niha ariwa, de ọwọ́ Hamati; wọnyi sa ni ihà rẹ̀ ni ila-õrun ati iwọ-õrun; ipin kan fun Dani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn: Ní òpin àríwá, Dánì yóò ni ìpín kan; èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hétílónù sí létí Hámátì; Hásárì Énánù àti ààlà àríwá tí Dámásíkù tí ó kángun sí Hámátì yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn.