Ezekiel 48:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo jẹ́ ti àwọn alufaa tí a yà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Sadoku tí wọ́n pa òfin mi mọ́, tí wọn kò sì ṣáko lọ bí àwọn ọmọ Lefi, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio jẹ ti awọn alufa ti a yà si mimọ́, ninu awọn ọmọ Sadoku; ti nwọn ti pa ilàna mi mọ, ti nwọn kò si ṣìna ni iṣìna awọn ọmọ Israeli, bi awọn Lefi ti ṣìna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí yóò wà fún àwọn àlùfáà tí a yà sí mímọ́, àwọn Sódókítì tí wọn jẹ́ olóòótọ́ nínú sí sin mí, ti wọn kò sì sáko lọ bí ti àwọn Léfì ṣe se nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì sáko lọ.