Ezekiel 48:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Lefi yóo ní ìpínlẹ̀ tiwọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tí a pín fún àwọn alufaa, òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni ikọjusi àgbegbe awọn alufa, ni awọn Lefi yio ni ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú: gigùn gbogbo rẹ̀ yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ati ibú rẹ̀, ẹgbã-marun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbégbé àwọn àlùfáà, àwọn Léfì yóò pín ìpín kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀. Gígùn rẹ̀ ní àpapọ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹẹdọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, àti fífẹ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́.