Ezekiel 48:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò gbọdọ̀ tà ninu rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi yáwó, wọn kò sì gbọdọ̀ fún ẹlòmíràn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ yìí; nítorí pé mímọ́ ni, ti OLUWA sì ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio si tà ninu rẹ̀, nwọn kì yio si fi ṣe paṣiparọ, bẹ̃ni nwọn kì yio si fi akọ́so ilẹ na si ọwọ́ ẹlomiran, nitoripe o jẹ mimọ́ fun Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò gbọdọ̀ tà tàbí jìrọ̀ ìkankan nínú rẹ̀. Èyí yìí ni ó dára jùlọ lára ilẹ náà, a kò sì gbọdọ̀ fifún ẹlòmíràn nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ fún OLÚWA.