Ezekiel 48:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà yóo gùn ní ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), ati ti ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati ti àríwá ati ti gúsù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi ni yio si jẹ iwọ̀n rẹ̀; ni ihà ariwa, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ̀nyí sì ní bi a ṣe wọ̀n ọ́n: ní ìhà àríwá ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ni ìhà gúsù ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ní ìhà ìlà oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ àti ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́.