Ezekiel 48:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ilẹ̀ tí ó kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, ati ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà. Èso ilẹ̀ náà yóo jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iyokù ni gigùn, ni ikọjusi ọrẹ ti ipin mimọ́ na, yio si jẹ ẹgbã-marun nihà ila-õrun, ati ẹgbã-marun nihà iwọ-õrun: yio si wà ni ikọjusi ọrẹ ipin mimọ́ na, ati ibisi rẹ̀ yio jẹ fun onjẹ fun awọn ti nsìn ni ilu-nla na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí tí ó kù ní agbégbé náà, tí ó jẹ́ ààlà ìpín ibi mímọ́, gígùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Ìpèsè rẹ̀ yóò fi kún oúnjẹ fún àwọn òsísẹ́ ìlú ńlá náà.