Ezekiel 48:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Juda ni ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo wà. Ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12.5), òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà pẹlu ti àwọn ìpín yòókù láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ibi mímọ́ yóo wà láàrin rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni àgbegbe Juda, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun ni yio jẹ ọrẹ ti ẹnyin o ta, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ije ni ibú, ati ni gigùn, bi ọkan ninu awọn ipin iyokù, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ààlà agbégbé Júdà láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì. Yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ (25,000) ní fífẹ̀, gígùn rẹ̀ láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn yóò jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ilé mímọ́ yóò wà ní àárin gbùngbùn rẹ̀.