Ezekiel 5:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Baba yóo máa pa ọmọ wọn jẹ láàrin yín; ọmọ yóo sì máa pa àwọn baba jẹ. N óo dájọ́ fun yín, n óo fọ́n gbogbo àwọn tí ó kù ninu yín káàkiri igun mẹrẹẹrin ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn baba yio jẹ awọn ọmọ li ãrin rẹ, ati awọn ọmọ yio si jẹ awọn baba wọn; emi o si ṣe idajọ ninu rẹ, ati gbogbo iyokù rẹ li emi o tuka si gbogbo ẹfũfù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà láàrin rẹ àwọn baba yóò má a jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. N ó jẹ ọ́ níyà, n ó sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú èfúùfù.