Ezekiel 5:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí mo ti wà láàyè, n óo pa yín run. N kò ní fojú fo ohunkohun, n kò sì ní ṣàánú yín rárá; nítorí ẹ ti fi àwọn nǹkan ẹ̀sìn ìríra ati àṣà burúkú yín sọ ilé mímọ́ mi di aláìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà; Nitõtọ, nitori ti iwọ ti sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́ nipa ohun ẹgbin rẹ, ati pẹlu gbogbo ohun irira rẹ, nitori na li emi o ṣe dín ọ kù, oju mi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ṣãnu fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, OLÚWA Ọlọ́run wí pé, bí mo ṣe wà láàyè, nítorí pé o ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, n ó mú ojú rere mi kúrò lára rẹ n kò ní í da ọ sí tàbí wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́.