Ezekiel 5:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn yóo pa ìdámẹ́ta lára yín, ogun tí yóo máa jà káàkiri yóo pa ìdámẹ́ta yín, n óo fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri gbogbo ayé, n óo sì gbógun tì wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idámẹta rẹ yio kú nipa ajakalẹ arùn, nwọn o si run li ãrin rẹ nipa iyàn, idámẹta yio si ṣubu nipa idà yi ọ ka kiri, emi o si tú idamẹta ká si gbogbo ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdá mẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-àrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdá mẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ n ó sì tú ìdá mẹ́ta yóòkù ká sínú èfúùfù, a ó sì máa fi idà lé wọn.