Ezekiel 5:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bẹ́ẹ̀ ni inú mi yóo ṣe máa ru si yín, tí n óo sì bínú si yín títí n óo fi tẹ́ ara mi lọ́rùn. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀ pẹlu owú nígbà tí mo bá bínú si yín tẹ́rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni ibinu mi o ṣẹ, emi o si mu ibinu mi duro lori wọn, inu mi yio si tutù: nwọn o si mọ̀ pe emi Oluwa ti sọ ọ ninu itara mi, nigbati mo ba pari ibinu mi ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbónná mi yóò sì rolẹ̀, n ó sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé Èmi OLÚWA ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi.