Ezekiel 5:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ óo di ẹni ẹ̀sín ati ẹni ẹ̀gàn, ẹni àríkọ́gbọ́n ati ẹni àríbẹ̀rù fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká; nígbà tí mo bá fi ibinu ati ìrúnú dájọ́ fun yín, tí mo sì jẹ yín níyà pẹlu ibinu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni yio si di ẹ̀gan ati ẹsín, ẹkọ́ ati iyanu si awọn orilẹ-ède ti o wà yi ọ ka kiri; nigbati emi o ṣe idajọ ninu rẹ ninu ibinu, ati ninu irunu on ibawi irunu. Emi Oluwa li o sọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ikílọ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi OLÚWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.