Ezekiel 5:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí mo bá ta ọfà burúkú mi si yín: ọfà ìyàn ati ọfà ìparun, tí n óo ta lù yín láti pa yín run, ìyàn óo mú lọpọlọpọ nígbà tí mo bá mú kí oúnjẹ yín tán pátá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati emi o rán ọfà buburu iyàn si wọn, eyi ti yio jẹ fun iparun wọn, eyi ti emi o rán lati run nyin: emi o si sọ iyàn di pupọ̀ fun nyin, emi o si ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo bá ta ọfà ikú àti ìparun pẹ̀lú ìyàn, n ó ta á láti run ọ́ ni. N ó gé ìpèsè oúnjẹ kúrò, n ó sì mú ìyàn wá lọ́pọ̀lọpọ̀.