Ezekiel 5:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jó ìdámẹ́ta rẹ̀ ninu iná láàrin ìlú, ní ìgbà tí ọjọ́ tí a fi dóti ìlú náà bá parí. Máa fi idà gé ìdámẹ́ta, kí o sì fọ́n ọn káàkiri lẹ́yìn ìlú, fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri sinu afẹ́fẹ́, n óo sì fa idà yọ tẹ̀lé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si fi iná sun idamẹta li ãrin ilu, nigbati ọjọ didotì ba pé: iwọ o si mu idamẹta, ki o si fi ọbẹ bù u kakiri: idamẹta ni iwọ o si tuka sinu ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ìrun yìí níná láàrin ìlú. Mú ìdá kan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdá kan yóòkù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká.