Ezekiel 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ti tàpá sí òfin mi ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ, ó sì ti kọ ìlànà mi sílẹ̀ ju àwọn agbègbè tí ó yí i ká lọ. Wọ́n kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ti pa idajọ mi dà si buburu ju awọn orilẹ-ède lọ, ati ilana mi ju ilẹ ti o yi i kakiri: nitori nwọn ti kọ̀ idajọ ati ilana mi, nwọn kò rìn ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ̀ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, kò sì pa ìlànà mi mọ́.