Ezekiel 5:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé rúdurùdu yín ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká lọ, ati pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Nitori ti ẹnyin ṣe ju awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri lọ, ti ẹnyin kò rìn ninu ilana mi, ti ẹ kò pa idajọ mi mọ, ti ẹ kò si ṣe gẹgẹ bi idajọ awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Nítorí pé o ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká lọ, tí o kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ tún ṣe dáadáa tó àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.