Ezekiel 5:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, èmi, OLUWA Ọlọrun fúnra mi, ni mo dójú le yín, n óo sì ṣe ìdájọ́ fun yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: kiye si i, Emi, ani Emi, doju kọ ọ, emi o si ṣe idajọ li ãrin rẹ li oju awọn orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jérúsálẹ́mù, n ó sì jẹ ọ́ níyà lójú àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.