Ezekiel 6:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa àwọn tí wọ́n wà lókèèrè; idà yóo pa àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ìyàn yóo sì pa àwọn yòókù tí ogun ati àjàkálẹ̀-àrùn bá dá sí. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o jina rere yio kú nipa ajakalẹ àrun; ati ẹniti o sunmọ tosí yio ṣubu nipa idà; ati ẹniti o kù ti a si do tì yio kú nipa iyàn: bayi li emi o mu irunu mi ṣẹ lori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni n ó ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn.