Ezekiel 6:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ káàkiri láàrin àwọn ère oriṣa wọn yíká pẹpẹ ìrúbọ wọn, ní gbogbo ibi ìrúbọ ati lórí gbogbo òkè ńlá, lábẹ́ gbogbo igi tútù ati gbogbo igi oaku eléwé tútù; ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí àwọn oriṣa wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati okú wọn yio wà larin ere wọn yi pẹpẹ wọn ka, lori oke kekeke gbogbo, lori ṣonṣo ori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo, ati labẹ gbogbo igi oaku bibò, ibiti nwọn ti rubọ õrùn didùn si gbogbo ere wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrin òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù-níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí dídùn rúbọ̀ sí gbogbo òrìṣà wọn.