Ezekiel 7:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ń tà kò ní sí láyé láti pada síbi ohun tí ó tà ní ìgbà ayé ẹni tí ó rà á. Nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn. Kò sì ní yipada, bẹ́ẹ̀ ni nítorí ẹ̀ṣẹ̀ olukuluku, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní sí láàyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori olùta kì yio pada si eyi ti a tà, bi wọn tilẹ wà lãye: nitori iran na kàn gbogbo enia ibẹ̀, ti kì yio pada; bẹ̃ni kò si ẹniti yio mu ara rẹ̀ le ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ontàjà kò ni ri ilé tó tà gbà níwọ̀n ìgbà ti awọ̀n méjèèjì bá wà láyé; torí ìran tó kan ènìyàn yìí kò ní yí padà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là.