Ezekiel 7:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo fọn fèrè ogun, wọn óo múra ogun, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò ní jáde lọ sójú ogun nítorí ibinu mi ti dé sórí gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ti fọn ipè, lati jẹ ki gbogbo wọn mura; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o lọ si ogun: nitori ibinu mi wà lori gbogbo wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọn tilẹ̀ fọn fèrè ogun tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, kò sẹ́ni tí yóò lọ ojú ogun, torí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn