Ezekiel 7:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí àwọn kan bá kù, tí wọn sá àsálà, wọn yóo dàbí àdàbà àfonífojì lórí àwọn òkè. Gbogbo wọn yóo máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn olukuluku yóo máa dárò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ti o bọ́ ninu wọn yio salà, nwọn o si wà lori oke bi adabà afonifoji, gbogbo nwọn o ma gbãwẹ, olukuluku nitori aiṣedede rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedédé rẹ̀.