Ezekiel 7:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n óo fọ́n fadaka wọn dà sílẹ̀ láàrin ìgboro. Wúrà wọn yóo sì dàbí ohun àìmọ́. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA. Kò ní lè tẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní lè jẹ ẹ́ yó. Nítorí pé wúrà ati fadaka ló mú wọn dẹ́ṣẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o sọ fadaka wọn si igboro, wura wọn li a o si mu kuro; fadaka wọn ati wura wọn kì yio si le gbà wọn là li ọjọ ibinu Oluwa: nwọn kì yio tẹ́ ọkàn wọn lọrùn, bẹ̃ni nwọn kì yio kún inu wọn; nitori on ni idùgbolu aiṣedede wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn ó dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn ó sì dàbí èérí ìdọ̀tí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná OLÚWA. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.