Ezekiel 7:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń lo ohun ọ̀ṣọ́ wọn dáradára fún ògo asán; òun ni wọ́n fi ń ṣe àwọn ère ati oriṣa wọn, àwọn ohun ìríra tí wọn ń bọ. Nítorí náà, OLUWA óo sọ wọ́n di ohun àìmọ́ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ṣe ti ẹwà ohun ọṣọ́ rẹ̀ ni, o gbe e ka ibi ọlanla: ṣugbọn nwọn yá ere irira wọn ati ohun ikorira wọn ninu rẹ̀: nitorina li emi ṣe mu u jina si wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn n ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀sọ́ wọn, tí ó lẹ́wà, wọn sì ti fi ṣe òrìṣà, wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀. Nítorí náà, ní o sọ àwọn ǹnkan wọ̀nyí di ohun èérí tabi ìdọ̀tí fún wọn.