Ezekiel 7:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo kó àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n burú jùlọ wá, wọn óo wá gba ilé wọn. N óo fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára wọn, wọn yóo sì sọ àwọn ibi mímọ́ wọn di eléèérí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li emi o mu awọn keferi ti o burujulọ, nwọn o si jogun ile wọn: emi o si mu ọṣọ-nla awọn alagbara tán pẹlu, ibi mimọ́ wọn li a o si bajẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè ti búburú rẹ pọ̀ jù gba ilé wọn; ń ó sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.