Ezekiel 7:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àjálù yóo máa yí lu àjálù, ọ̀rọ̀ àhesọ yóo máa gorí ara wọn. Wọn yóo máa wo ojú wolii fún ìran ṣugbọn kò ní sí, alufaa kò ní náání òfin mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìmọ̀ràn mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tulasì yio gori tulasi, irọkẹ̀kẹ yio si gori irọkẹ̀kẹ; nigbana ni nwọn o bere lọdọ woli; ṣugbọn ofin yio ṣegbé kuro lọdọ alufa, ati imọ̀ kuro lọdọ awọn agbà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì sókè lórí ìdágìrì, Nígbà náà ni wọn ó wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì; ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn alàgbà.